oba awon oba - hibeekay lyrics
omobadeji:
kabiyesi olodumare ekun oko oke pharaoh
oba nla ti nfi oba je
oba to ju oba lo, oba awon oba
aterere kari aye, atorise, ameda aweda aseda
emi o to lati yin o o, olorun awon baba wa
ti nje emi ni, emi ni, emi ni mo ke kabiyesi o
oba awon oba, oba awon oba oba awon oba, oba awon oba
all: oba awon oba, oba awon oba till fade…….
hibeekay:
tani eni ti o ba esu wi
to da aye ati orun
gbongbo idile jese
akobi ninu awon oku
kiniu eya juda
apata ayeraye
ologo didan ni
kabio osi olorun
olowogbogboro ni
ti nyo omo re lofin aye
alagbada ina
oba ayeraye
oba ti o la omi okun pupa
to gba omo israeli
lowo ogun pharaoh
awon ara egipti
oba to ju oba lo
ibeere ati opin
olorun abraham
olorun isaaki
olorun jakobu
olorun dafidi
akin omo akin:
oba aja bi iji
olorun ailopin
agbafefe sola
pari pari aye
eni mimo ola
onibudo eye
aara wawa nwowoo
pitu pitu ola
adakeroro seun lile
oba akoda aye
oba aseda orun
akiikitan ayiinyintan
iwo naa ni
oba tole logun
mimo mimo mimo
eleburu ike
oba onibu ola
oba onibu ore
akasebijo bawon wi
ipa lori ipa
abani dinbe lai jeran
ajanaku ode orun
weli weli bi ejiinpani
funfun nini lode orun
akobi akorii
ako oju tole logun
oba aseyi to fe
asegun ma lo ibon
oke ninu ogbun
odaada tii ri da
odaada tii ri da
dagi lekun esoo
agba ninu eko
onibudo eye
aboni ma jeun
afuye bi ewe
awuwo bi erin
kabiyesi ode orun
afoba joba
ganaku bi oyun
gulutu bi omo
agbek*mi ma bi
olori oloore
gboun gboun bi owuu lurin
akeni bi oju
atoni bi omo
kosoba bi ire
aponni ma gba oja
asoni ma sun lo
oba ayeraye
titi lae lae lae lae lae lae lae lae lae ni un o ma yin o nigbagbogbo…
Random Song Lyrics :
- tre sorelle - alessio lega lyrics
- shot in the heart - genya ravan lyrics
- nobody - cooley47 lyrics
- another one - killbzy lyrics
- недоступен (unavailable) - minay lyrics
- no kissing - vegas ace lyrics
- polvo blanco - bremont 420 lyrics
- балдеж (baldej) - кузьма гридин (kuzma gridin) lyrics
- tentang kita - langit sore lyrics
- gangorra - tibagi e niltinho lyrics